Iba'se - The Ifa Prayer of Praise
Ope ni fun Olorun,
Iba Olodumare, Oba ajiki,
Mo ji loni,
Mo wo'gun merin Aye,
Iba Elawori,
Agbegi lere, la'fin ewu l'ado,
Eiti Olodumare ko pa'jo iku e da,
Omo Oluworiogbo,
Iba'se ila Oorun,
Iba'se iwo Oorun,
Iba'se Ariwa,
Iba'se Guusu,
Iba Oba Igbalaye,
Iba Orun Oke,
Iba Atiwo Orun,
Iba Olokun a-soro-dayo,
Iba afefe legelege awo isalu-aye,
Iba Ogege, Oba ti ngb'aiye gun,
Iba titi aiye lo gbere,
Iba Oba awon Oba,
Iba Okiti biri, Oba ti np'ojo iku da,
Iba ate-ika eni Olodumare,
Iba Odemu demu kete a lenu ma fohun,
Iba Ori,
Iba Ori inu,
Iba Iponri ti o wa l'Orun,
Iba Kori,
Iba Ajala-Mopin,
Iba Aludundun-Orun,
Iba Odo-Aro, ati Odo-Eje,
Orun Ori nile, e oo jiyin, e oo jabo oun ti e ri,
Iba Esu Odara, Okunrin ori ita, ara Oke Itase, ao fi ida re lale,
Iba Osoosi ode mata,
Iba Ogun awo,
Onile kangu-kangu Orun,
Iba Obatala, Orisa Osere Igbo,
Oni kutukutu awo owuro,
Orisa Osere Igbo,
Iku ike,
Oba pata-pata ti nba won gb'ode iranje,
Iba Yemoja Olugbe-rere,
Iba Osun oloriya igun arewa obirin,
Iba Olukoso aira, bambi omo arigba ota segun,
Iba Ajalaiye Ajalorun Oya Oluweku,
Iba Aje-oguguluso Olambo yeye aiye,
Iba Awon Iyaami,
Alagogo eiswu a p'oni ma hagun,
Iba Orunmila, Eleri ipin,
Iku dudu atewo,
Oro to si gbogbo ona,
Iba Awo Akoda,
Iba Awo Aseda,
Iba Ojubo onomefa
Ase